Ramadan
Ìkan nínú àwọn àyọkà lórí |
Ìmàle |
Ìgbàgbọ́ |
---|
Allah · Ọ̀kanlọ̀kan Ọlọ́run · Àwọn Ànábì · Revealed books · Àwọn Mọ̀láíkà |
Àwọn ojúṣe |
Àwẹ̀ · Ìṣọrẹ · Ìrìnàjò |
Ìwé àti òfin |
Fiqh · Sharia · Kalam · Sufism |
Ìtàn àti olórí |
Timeline · Spread of Islam Imamate |
Àṣà àti àwùjọ |
Academics · Animals · Art Mọ́ṣálásí · Ìmòye Sáyẹ́nsì · Àwọn obìnrin Ìṣèlú · Dawah |
Ẹ̀sìn ìmàle àti àwọn ẹ̀sìn yìókù |
Hinduism · Sikhism · Jainism · Mormonism |
Ẹ tún wo |
Glossary of Islamic terms |
Èbúté Ìmàle |
Ramadan (Ramzan, Ramadhan tàbí Ramathan) jẹ́ oṣù kẹsàn-án nínú ònkà oṣù ojú ọ̀run ẹ̀sìn Ìmàle.[1] Gbogbo ẹlẹ̀sìn Islam ninwọ́n ma ń gba àwẹ̀ nínú oṣù Ramadan jákè-jádò agbáyé, tí wọ́n sì ma ń kún fún bíbẹ Ọlọ́run púpọ̀ jùlọ.[2][3] Gbígba awẹ̀ nínú oṣù Ramadan lọ́dọọdún jẹ́ ìkan nínú Àwọn Òpó Márùún Ìmàle. [4] Wọ́n ma ń gba awẹ̀ nínú oṣù Ramadan fún ọgbọ̀n ọjọ́ tàbí ọjọ́ mọ́kàndílọ̀gbọ̀n. Bíbẹ̀rẹ̀ awẹ̀ ma ń dá lé bí wọ́n bá ṣe rí ìlétéṣù lójú ọ̀run níparí oṣù Sha'abán. Bí wọ́n bá sì fẹ́ túnu, wọn yóò ma wòye ojú ọjọ́ fún lílé oṣù oṣù Shawwal tàbí kí Won ka àwẹ̀ Ramadan pe ọgbọ̀n gbáko kí wọ́n tó dáwọ́ Awẹ̀ dúró.[5][6] Gbígbàwẹ̀ láti òwúrọ̀ kùtùkùtù tí tí di ìgbà tí Oòrùn bá ti wọ̀ tán, jẹ́ dan dan fún gbogbo Mùsùlùmí tí wọ́n ti bàlágà yí wọ́n kò sì ní ìṣòro àárẹ̀, tàbí àìsàn tó lágbára, tí wọn kò sì sí ní inú ìrìn-àjò tó lágbára, tí wọn kò sì kìí ṣe arúgbò kùjọ́ kùjọ́, bákan náà tí wọn kò sì kìí ṣe abiyamọ tí wọ́n ń fọmọ lóyàn tàbí ṣe nkan oṣù lọ́wọ́. [7] Oúnjẹ tí wọ́n ma ń jẹ ní ìdájí ni wọn ń pe ní Sààrì nígbà tí oúnjẹ tí wọ́n ma ń jẹ tí wọ́n fi ń ṣínu ni wọ́n ń pe ní ìṣínu.[8][9].
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn itọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ BBC – Religions Archived 28 July 2012 at the Wayback Machine. Retrieved 25 July 2012
- ↑ "Ramadan: Fasting and Traditions". Archived from the original on 22 March 2019. Retrieved 6 May 2019. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Ramadan 2020: Date, importance, wishes, quotes, messages, and pictures". India Today.
- ↑ "Schools – Religions". BBC. Archived from the original on 27 August 2012. Retrieved 25 July 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Bukhari-Ibn-Ismail, AbdAllah-Muhammad. "Sahih Bukhari – Book 031 (The Book of Fasting), Hadith 124.". hadithcollection.com. Archived from the original on 13 June 2012. Retrieved 25 July 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Muslim-Ibn-Habaj, Abul-Hussain. "Sahih Muslim – Book 006 (The Book of Fasting), Hadith 2378.". hadithcollection.com. Archived from the original on 15 January 2013. Retrieved 25 July 2012. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Fasting (Al Siyam) – الصيام – p. 18, el Bahay el Kholi, 1998
- ↑ Islam, Andrew Egan – 2002 – p. 24
- ↑ Dubai – p. 189, Andrea Schulte-Peevers – 2010