Jump to content

Angus Fraser

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Angus Fraser MFR (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹrin ọdún 1931, tí ó sì kú ní ọjọ́ keje, oṣù kẹwàá ọdún 2019) jẹ́ Àlùfáà tí ìjọ Catholic, onímọ̀ àti olùdásílẹ̀ Via Christi Society, ẹ̀ni tí ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ fún ìlọ́wọ́sí ̀tò-ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Fraser sí Cane Cove Grove House, St. Vincent Island, Caribbean. Ó dàgbà sí ìdílé àwọn ará Anglican. Ìbápàdé rẹ̀ pẹ̀lú ìjọ Catholic lásìkò tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní St. Vincent Grammar School ló mu kí ó yí padà láti máa lọ sí ìjọ Vatholic. Fraser tiraka láti kàwé jáde ní Mt. St. Benedict’s secondary school, Tunapuna, èyí tó jé ilé-ìwe tí àwọn Mọ́ǹkù láti College of the Benedictine ń ṣàkóso. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní St Mary’s College, Port of Spain, Trinidad, kí ó tó wá di pé ó gba iṣẹ́ Àlùfáà ní pẹrẹu, pẹ̀lú àwọn Bàbá ti ẹ̀mí mímọ́ lẹ́yìn ẹ̀ḱ rẹ̀ nínú Philosophy àti Theology àti ìfàmì-òróró-yàn rẹ̀ láti ọwọ́ John Charles McQuaid ti Dublin, ní Ireland ní ọdún 1959.[1]

Ìrìn àjò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ránṣẹ́ orí pápá bẹ̀rẹ̀ nígbà tó dé sí Diocese ti Owerri, Nàìjíríà, ní ọdún 1961. Àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ kún fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ìjọ Our Lady of Fatima ni Kano àti àwọn irú iṣẹ́ ìránṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lábẹ́ àwọn ẹni jàǹkàn-jàǹkàn bí Bíṣọ́ọ́bù Godfrey Okoye àti Bíṣọ́ọ́bù Francis Cardinal Arinze. Nígbà àkọ́kọ́ rẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Port Harcourt, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé, olùkọ́ àti lítúgíìstì.[2]

Fraser gba ipò ọ̀gá ilé ìwé ni ilé ìwé gírámà ti Mt. St. Gabriel Fraser ni ìlú Makurdi ní ọdún 1971. Ó ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́talélógójì kí ó tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́.[3] Lára àwọn tí ó kọ́ ni olùdarí ìgbìmọ̀ Nàìjíríà ti tẹ́lẹ̀ àti mínísítà ilé ìgbìmọ̀, Iyorchia Ayu, olórí àwọn agbẹjọ́rọ̀ tí orílè èdè tí tẹ́lẹ̀, Michael Aondoakaa, olórin ìdárayá, Tuface Idibia àti ìránṣẹ́ Ọlọ́run William Avenya.[4]

Ibi Ìsìnkú Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fraser ti sọ ìfẹ́ inú rẹ̀ pé ó wù ú pé kí wọn sì òun sí Garkwaa, ní Ìpínlẹ̀ Plateau, ibi tí ó kó lọ lẹ́yìn tí ó kúrò ní àwọn ipò adarí rẹ̀ ní àwùjọ Via Christian àti Orí-Òkè Saint Gabriel ni ọdún 2014. Àwọn ẹbí rẹ̀ fẹ́ láti sìn sí St. Vincent & the Grenadines. Àwọn olórí ẹgbẹ́ àgbègbè da lába pé kí wọ́n sìn sí Lọ́ńdọ́nù tàbí Aliade, nibi ti àwọn bàbá tó ní Ẹ̀mí Mímọ́ ti ní ìjọ. Ṣùgbọ́n, Rọ́mù fún wọn láyè láti sín sí ilẹ̀ Orí-Òkè Saint Gabriel ni Ìpínlẹ̀ Makurdi.[5]

Ní ọdún 2003, Fraser gba àmì ẹ̀yẹ pé ó di ọmọ orílẹ̀ èdè (MFR) lọ́wọ́ Ààrẹ Olusegun Obasanjo. A tún mọ rírì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí "Olùkọ́ tí ó dára jù lọ ní Nàìjíríà", ó sì tún gba "Àmì Ẹ̀yẹ pé ó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ṣe àṣeyọrí" lọ́wọ́ Ààrẹ Bill Clinton, Ààrẹ ti tẹ́lẹ̀ ni orílẹ̀-èdè US.[6][7]

Àwọn Ìtọ́kási

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Meet our founder". viachristisociety.org. Via Christi Society. Retrieved 4 January 2024. 
  2. Admin, C. N. (7 December 2018). "Fr Angus – a saintly legend". CatholicTT. catholictt.org. Retrieved 4 January 2024. 
  3. "MSGOBA | About". msgoba.com. Retrieved 4 January 2024. 
  4. "Breaking: Longest serving teacher, missionary in Nigeria, dies". vanguardngr.com. 9 October 2018. https://www.vanguardngr.com/2018/10/breaking-longest-serving-teacher-missionary-in-nigeria-dies/#:~:text=In%202003%2C%20Fraser%20was%20given,the%20“Best%20Teacher%20in%20Nigeria.. 
  5. "Rev Fr. Angus Fraser, Legendary Principal of Mt St Gabriel’s Gets A Resting Place @ Last". Intervention. intervention.ng. 24 November 2018. Retrieved 4 January 2024. 
  6. Editorial Staff (10 October 2018). "Nigeria’s Longest-Serving Teacher Vincentian Angus Fraser Dies". St Vincent Times. stvincenttimes.com. Retrieved 4 January 2024. 
  7. Chinyem, Valentine (10 October 2018). "Longest serving school Principal and Missionary in Nigeria is dead". News Of Nigeria. Archived from the original on 5 January 2024. https://web.archive.org/web/20240105010744/https://newsofnigeria.com/longest-serving-school-principal-and-missionary-in-nigeria-is-dead/.